@yetundeinherited: Psalm 124 in Yoruba ❤️ Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa” ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí; 2 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,” Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa: 3 Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa 4 Nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀ 5 Nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa. 6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn. 7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ. 8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé. #yetundeinherited #cherubimandseraphimworldwide #cherubimandseraphim #thanksgiving