@whoisasake: Ẹ fi ẹnu túnmiṣe Ẹnu ni abẹ́rẹ́ fi ń tún aṣọ ṣe A kìí la pópó ká má kan ilé A kìí là ọ̀nà ká má kan ọjà A kìí gbé àwòrán gàgàrà Ká má fi ọwọ́ rẹ̀ tì síbìkan A Dífá fún Yéwándé Nígbà tó máa bí Ó bí ọ̀wẹ́rẹ́ lọ́mọ Nígbà tó máa bí Ó bí ọ̀gbàrá lọ́mọ Àwọn méjèèjì sùn Wọ́n forí lé elébútú Wọ́n pa elébútú jẹ Òkú kìí wọ́n lóde Ọ̀jọ̀jọ̀ Gbogbo ẹni tó bá ń pe orí mi níbi Ikú oró ni kí wọ́n máa kú Inú ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ni kí wọ́n máa sùn Nítorí ẹnìkan kìí bá omi ṣọ̀tá Omi la bùwẹ̀ Omi la bù mu Ẹnìkan kìí bá omi ṣọ̀tá #yorubatiktok #iwureowuro